1. ỌMỌ mi, bi iwọ ba ṣe onigbọwọ fun ọrẹ́ rẹ, bi iwọ ba jẹ́ ẹ̀jẹ́ fun ajeji enia.
2. Bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ dẹkùn fun ọ, bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ mu ọ.
3. Njẹ, sa ṣe eyi, ọmọ mi, ki o si gbà ara rẹ silẹ nigbati iwọ ba bọ si ọwọ ọrẹ́ rẹ; lọ, rẹ ara rẹ silẹ, ki iwọ ki o si tù ọrẹ́ rẹ.
4. Máṣe fi orun fun oju rẹ, tabi õgbe fun ipenpeju rẹ.
5. Gbà ara rẹ bi abo agbọnrin li ọwọ ọdẹ, ati bi ẹiyẹ li ọwọ apẹiyẹ.