7. Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi.
8. Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀:
9. Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka;
10. Ki a má ba fi ọrọ̀ rẹ fun ajeji enia; ki ère-iṣẹ ọwọ rẹ ki o má ba wà ni ile alejo.
11. Iwọ a si ma kãnu ni ikẹhin rẹ̀, nigbati ẹran-ara ati ara rẹ ba parun.
12. Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi: