Owe 4:6-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Máṣe kọ̀ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ́: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ́.

7. Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye.

8. Gbé e ga, on o si ma gbé ọ lekè: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra.

9. On o fi ohun-ọṣọ́ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ.

10. Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọ̀rọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ.

11. Emi ti kọ́ ọ li ọ̀na ọgbọ́n; emi ti mu ọ tọ̀ ipa-ọ̀na titọ.

12. Nigbati iwọ nrìn, ọ̀na rẹ kì yio há fun àye; nigbati iwọ nsare, iwọ kì yio fi ẹsẹ kọ.

13. Di ẹkọ́ mu ṣinṣin, máṣe jẹ ki o lọ; pa a mọ́, nitori on li ẹmi rẹ.

14. Máṣe bọ si ipa-ọ̀na enia buburu, má si ṣe rìn li ọ̀na awọn enia ibi.

15. Yẹ̀ ẹ silẹ, máṣe kọja ninu rẹ̀, yẹ̀ kuro nibẹ, si ma ba tirẹ lọ.

16. Nitoriti nwọn kì isùn bikoṣepe nwọn hùwa buburu; orun wọn a si dá, bikoṣepe nwọn ba mu enia ṣubu.

17. Nitori ti nwọn njẹ onjẹ ìwa-ika, nwọn si nmu ọti-waini ìwa-agbara.

18. Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan.

19. Ọna awọn enia buburu dabi òkunkun: nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn ndugbolu.

Owe 4