Owe 4:17-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nitori ti nwọn njẹ onjẹ ìwa-ika, nwọn si nmu ọti-waini ìwa-agbara.

18. Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan.

19. Ọna awọn enia buburu dabi òkunkun: nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn ndugbolu.

20. Ọmọ mi, fetisi ọ̀rọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọ̀rọ mi.

21. Máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ; pa wọn mọ́ li ãrin aiya rẹ.

22. Nitori ìye ni nwọn iṣe fun awọn ti o wá wọn ri, ati imularada si gbogbo ẹran-ara wọn.

23. Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye.

24. Mu arekereke kuro lọdọ rẹ, ati ète ẹ̀tan jina rére kuro lọdọ rẹ.

25. Jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ọkankan gan, ki ipenpeju rẹ ki o ma wò gan niwaju rẹ.

Owe 4