Owe 4:13-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Di ẹkọ́ mu ṣinṣin, máṣe jẹ ki o lọ; pa a mọ́, nitori on li ẹmi rẹ.

14. Máṣe bọ si ipa-ọ̀na enia buburu, má si ṣe rìn li ọ̀na awọn enia ibi.

15. Yẹ̀ ẹ silẹ, máṣe kọja ninu rẹ̀, yẹ̀ kuro nibẹ, si ma ba tirẹ lọ.

16. Nitoriti nwọn kì isùn bikoṣepe nwọn hùwa buburu; orun wọn a si dá, bikoṣepe nwọn ba mu enia ṣubu.

17. Nitori ti nwọn njẹ onjẹ ìwa-ika, nwọn si nmu ọti-waini ìwa-agbara.

18. Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan.

19. Ọna awọn enia buburu dabi òkunkun: nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn ndugbolu.

20. Ọmọ mi, fetisi ọ̀rọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọ̀rọ mi.

21. Máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ; pa wọn mọ́ li ãrin aiya rẹ.

Owe 4