1. ENYIN ọmọ, ẹ gbọ́ ẹkọ́ baba, ki ẹ si fiyesi ati mọ̀ oye.
2. Nitori ti mo fun nyin li ẹkọ rere, ẹ máṣe kọ̀ ofin mi silẹ.
3. Nitoripe ọmọ baba mi li emi iṣe, ẹni-ikẹ́ ati olufẹ li oju iya mi.
4. On si kọ́ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọ̀rọ mi duro: pa ofin mi mọ́ ki iwọ ki o si yè.
5. Ni ọgbọ́n, ni oye: máṣe gbagbe; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fà sẹhin kuro li ọ̀rọ ẹnu mi.
6. Máṣe kọ̀ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ́: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ́.
7. Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye.