1. ENYIN ọmọ, ẹ gbọ́ ẹkọ́ baba, ki ẹ si fiyesi ati mọ̀ oye.
2. Nitori ti mo fun nyin li ẹkọ rere, ẹ máṣe kọ̀ ofin mi silẹ.
3. Nitoripe ọmọ baba mi li emi iṣe, ẹni-ikẹ́ ati olufẹ li oju iya mi.
4. On si kọ́ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọ̀rọ mi duro: pa ofin mi mọ́ ki iwọ ki o si yè.
5. Ni ọgbọ́n, ni oye: máṣe gbagbe; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fà sẹhin kuro li ọ̀rọ ẹnu mi.
6. Máṣe kọ̀ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ́: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ́.
7. Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye.
8. Gbé e ga, on o si ma gbé ọ lekè: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra.
9. On o fi ohun-ọṣọ́ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ.
10. Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọ̀rọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ.