Owe 31:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Fi ọti lile fun ẹniti o mura tan lati ṣegbe, ati ọti-waini fun awọn oninu bibajẹ.

7. Jẹ ki o mu, ki o si gbagbe aini rẹ̀, ki o má si ranti òṣi rẹ̀ mọ́.

8. Yà ẹnu rẹ fun ayadi, ninu ọ̀ran gbogbo ẹniti iṣe ọmọ iparun.

9. Yà ẹnu rẹ, fi ododo ṣe idajọ, ki o si gbèja talaka ati alaini.

10. Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn.

11. Aiya ọkọ rẹ̀ gbẹkẹle e laibẹ̀ru, bẹ̃ni on kì yio ṣe alaini ère iṣẹ.

12. Rere li obinrin na yio ma ṣe fun u, kì iṣe buburu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo.

13. Obinrin na yio ma ṣafẹri kubusu ati ọ̀gbọ, o si fi ọwọ rẹ̀ ṣiṣẹ tinutinu.

14. O dabi ọkọ̀ oniṣowo: o si mu onjẹ rẹ̀ lati ọ̀na jijin rére wá.

Owe 31