19. O fi ọwọ rẹ̀ le kẹkẹ́-owú, ọwọ rẹ̀ si di ìranwu mu.
20. O nà ọwọ rẹ̀ si talaka; nitõtọ, ọwọ rẹ̀ si kàn alaini.
21. On kò si bẹ̀ru òjo-didì fun awọn ara ile rẹ̀; nitoripe gbogbo awọn ara ile rẹ̀ li a wọ̀ li aṣọ iṣẹpo meji.
22. On si wun aṣọ titẹ́ fun ara rẹ̀; ẹ̀wu daradara ati elese aluko li aṣọ rẹ̀.
23. A mọ̀ ọkọ rẹ̀ li ẹnu-bode, nigbati o ba joko pẹlu awọn àgba ilẹ na.
24. O da aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si tà a, pẹlupẹlu o fi ọjá amure fun oniṣòwo tà.
25. Agbara ati iyìn li aṣọ rẹ̀; on o si yọ̀ si ọjọ ti mbọ.