Owe 30:3-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Emi kò tilẹ kọ́ ọgbọ́n, emi kò tilẹ ni ìmọ ohun mimọ́.

4. Tali o ti gòke lọ si ọrun, tabi ti o si sọkalẹ wá? tali o kó afẹfẹ jọ li ọwọ rẹ̀? tali o di omi sinu aṣọ; tali o fi gbogbo opin aiye le ilẹ? Orukọ rẹ̀ ti ijẹ, ati orukọ ọmọ rẹ̀ ti ijẹ, bi iwọ ba le mọ̀ ọ?

5. Gbogbo ọ̀rọ Oluwa jẹ́ otitọ: on li asà fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le e.

6. Iwọ máṣe fi kún ọ̀rọ rẹ̀, ki on má ba ba ọ wi, a si mu ọ li eke.

7. Ohun meji ni mo tọrọ lọdọ rẹ; máṣe fi wọn dù mi ki emi to kú.

8. Mu asan ati eke jìna si mi: máṣe fun mi li òṣi, máṣe fun mi li ọrọ̀; fi onjẹ ti o to fun mi bọ mi.

9. Ki emi ki o má ba yó jù, ki emi ki o má si sẹ́ ọ, pe ta li Oluwa? tabi ki emi má ba tòṣi, ki emi si jale, ki emi si ṣẹ̀ si orukọ Ọlọrun mi.

Owe 30