Owe 30:15-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Eṣúṣu ni ọmọbinrin meji, ti nkigbe pe, Muwá, muwá. Ohun mẹta ni mbẹ ti a kò le tẹ lọrùn lai, ani mẹrin kì iwipe, o to.

16. Isa-okú, ati inu àgan; ilẹ ti kì ikún fun omi; ati iná ti kì iwipe, o to.

17. Oju ti o sin baba rẹ̀ jẹ, ti o gàn ati gbọ́ ti iya rẹ̀, kanakáná ẹba odò ni yio yọ ọ jade, ọmọ idì a si mu u jẹ.

18. Ohun mẹta ni mbẹ ti o ṣe iyanu fun mi, nitõtọ, mẹrin li emi kò mọ̀.

19. Ipa idì loju ọrun; ipa ejò lori apata: ipa ọkọ̀ loju okun; ati ìwa ọkunrin pẹlu wundia.

20. Bẹ̃ni ìwa agbere obinrin: o jẹun, o si nù ẹnu rẹ̀ nù, o si wipe, emi kò ṣe buburu kan.

21. Nitori ohun mẹta, aiye a di rũru, ati labẹ mẹrin ni kò le duro.

22. Iranṣẹ, nigbati o jọba; ati aṣiwère, nigbati o yo fun onjẹ;

23. Fun obinrin, ti a korira, nigbati a sọ ọ di iyale; ati fun iranṣẹbinrin, nigbati o di arole iya rẹ̀.

24. Ohun mẹrin ni mbẹ ti o kerejù lori ilẹ, sibẹ nwọn gbọ́n, nwọn kọ́ni li ẹkọ́.

25. Alailagbara enia li ẽra, ṣugbọn nwọn a pese onjẹ wọn silẹ ni ìgba ẹ̀run.

26. Alailagbara enia li ehoro, ṣugbọn nwọn a ṣe ìho wọn ni ibi palapala okuta.

27. Awọn ẽṣú kò li ọba, sibẹ gbogbo wọn a jade lọ li ọwọ́-ọwọ́;

28. Ọmọle fi ọwọ rẹ̀ dì mu, o si wà li ãfin awọn ọba.

29. Ohun mẹta ni mbẹ ti nrìn rere, nitõtọ, mẹrin li o dára pupọ ni ìrin rirìn:

30. Kiniun ti o lagbara julọ ninu ẹranko, ti kò si pẹhinda fun ẹnikan;

31. Ẹṣin ti a dì lẹgbẹ; ati obukọ; ati ọba larin awọn enia rẹ̀.

32. Bi iwọ ba ti ṣiwère ni gbigbe ara rẹ soke, tabi bi iwọ ba ti ronú ibi, fi ọwọ rẹ le ẹnu rẹ.

Owe 30