Owe 30:10-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Máṣe fi iranṣẹ sùn oluwa rẹ̀, ki o má ba fi ọ bu, ki iwọ má ba jẹbi.

11. Iran kan wà ti nfi baba rẹ̀ bu, ti kò si sure fun iya rẹ̀.

12. Iran kan wà, ti o mọ́ li oju ara rẹ̀, ṣugbọn a kò ti iwẹ̀ ẹ nù kuro ninu ẽri rẹ̀.

13. Iran kan wà, yẽ, oju rẹ̀ ti gbega to! ipenpeju rẹ̀ si gbé soke.

14. Iran kan wà, ehin ẹniti o dabi idà, erigi rẹ̀ dabi ọbẹ, lati jẹ talaka run kuro lori ilẹ, ati awọn alaini kuro ninu awọn enia.

15. Eṣúṣu ni ọmọbinrin meji, ti nkigbe pe, Muwá, muwá. Ohun mẹta ni mbẹ ti a kò le tẹ lọrùn lai, ani mẹrin kì iwipe, o to.

Owe 30