Owe 28:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ENIA buburu sá nigbati ẹnikan kò le e: ṣugbọn olododo laiya bi kiniun.

2. Nipa irekọja ilẹ li awọn ijoye idi pupọ, ṣugbọn nipa amoye ati oni ìmọ̀ enia kan, li a mu ilẹ pẹ.

3. Olupọnju ti o nni olupọnju lara, o dabi agbalọ òjo ti kò fi onjẹ silẹ.

4. Awọn ti o kọ̀ ofin silẹ a ma yìn enia buburu: ṣugbọn awọn ti o pa ofin mọ́ a ma binu si wọn.

5. Oye idajọ kò ye enia buburu: ṣugbọn awọn ti nṣe afẹri Oluwa moye ohun gbogbo.

6. Talaka ti nrin ninu iduro-ṣinṣin rẹ̀, o san jù alarekereke ìwa, bi o tilẹ ṣe ọlọrọ̀.

7. Ẹnikẹni ti o pa ofin mọ́, o ṣe ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ṣe ẹlẹgbẹ jẹguduragudu, o dojuti baba rẹ̀.

8. Ẹniti o fi elé ati ère aiṣõtọ sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di pupọ, o kó o jọ fun ẹniti yio ṣãnu fun awọn talaka.

9. Ẹniti o mu eti rẹ̀ kuro lati gbọ́ ofin, ani adura rẹ̀ pãpa yio di irira.

10. Ẹnikẹni ti o mu olododo ṣìna si ọ̀na buburu, ontikararẹ̀ yio bọ si iho, ṣugbọn aduro-ṣinṣin yio jogun ohun rere.

Owe 28