7. Ọkàn ti o yó fi ẹsẹ tẹ afara-oyin; ṣugbọn ọkàn ti ebi npa, ohun kikoro gbogbo li o dùn.
8. Bi ẹiyẹ ti ima fò kiri lati inu itẹ́ rẹ̀, bẹ̃li enia ti o nrìn kiri jina si ipò rẹ̀.
9. Ororo ati turari mu ọkàn dùn: bẹ̃ni adùn ọrẹ ẹni nipa ìgbimọ atọkànwa.
10. Ọrẹ́ rẹ ati ọrẹ́ baba rẹ, máṣe kọ̀ silẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe lọ si ile arakunrin li ọjọ idãmu rẹ: nitoripe aladugbo ti o sunmọ ni, o san jù arakunrin ti o jina rere lọ.