Owe 27:19-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Bi oju ti ikò oju li omi, bẹ̃li aiya enia si enia.

20. Ipò-okú ati iparun kì ikún, bẹ̃ni kì isu oju enia.

21. Bi koro fun fadaka, ati ileru fun wura, bẹ̃li enia si iyìn rẹ̀.

22. Bi iwọ tilẹ fi ọmọri-odó gún aṣiwère ninu odo larin alikama, wère rẹ̀ kì yio fi i silẹ.

23. Iwọ ma ṣaniyan ati mọ̀ ìwa agbo-ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọwọ-ẹran rẹ.

24. Nitoripe ọrọ̀ ki iwà titi lai: ade a ha si ma wà de irandiran?

25. Koriko yọ, ati ọmunú koriko fi ara han, ati ewebẹ̀ awọn òke kojọ pọ̀.

Owe 27