Owe 26:9-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Bi ẹgún ti igún ọmuti lọwọ, bẹ̃li owe li ẹnu awọn aṣiwère.

10. Bi tafatafa ti o mu gbogbo enia gbọgbẹ, bẹ̃ni ẹniti o gbà aṣiwère si iṣẹ, ti o si gba awọn olurekọja si iṣẹ-owo.

11. Bi aja ti ipada sinu ẽbì rẹ̀, bẹ̃li aṣiwère itun pada sinu wère rẹ̀.

12. Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.

13. Ọlẹ enia wipe, Kiniun mbẹ li ọ̀na; kiniun mbẹ ni igboro.

14. Bi ilẹkun ti iyi lori ìwakun rẹ̀, bẹ̃li ọlẹ lori ẹní rẹ̀.

15. Ọlẹ pa ọwọ rẹ̀ mọ́ sinu iṣãsun; kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu rẹ̀.

Owe 26