12. Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
13. Ọlẹ enia wipe, Kiniun mbẹ li ọ̀na; kiniun mbẹ ni igboro.
14. Bi ilẹkun ti iyi lori ìwakun rẹ̀, bẹ̃li ọlẹ lori ẹní rẹ̀.
15. Ọlẹ pa ọwọ rẹ̀ mọ́ sinu iṣãsun; kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu rẹ̀.
16. Ọlẹ gbọ́n li oju ara rẹ̀ jù enia meje lọ ti nwọn le fi ọgbọ́n dahùn ọ̀ran.
17. Ẹniti nkọja lọ, ti o si dasi ìja ti kì iṣe tirẹ̀, o dabi ẹniti o mu ajá leti.
18. Bi asiwin ti nsọ ọ̀kọ, ọfa ati ikú,
19. Bẹ̃li ẹniti o tan ẹnikeji rẹ̀ jẹ, ti o si wipe, Iré ha kọ li emi nṣe?
20. Nigbati igi tan, ina a kú, bẹ̃ni nigbati olofofo kò si, ìja a da.
21. Bi ẹyin ti ri si ẹyin-iná, ati igi si iná; bẹ̃li enia onijà lati da ìja silẹ.
22. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.
23. Ete jijoni, ati aiya buburu, dabi idarọ fadaka ti a fi bò ìkoko.
24. Ẹniti o ba korira, ti o fi ète rẹ̀ ṣe agabagebe, yio si pa ẹ̀tan mọ́ ninu rẹ̀.
25. Nigbati o ba sọ̀rọ daradara, máṣe gbà a gbọ́: nitoripe irira meje li o wà li aiya rẹ̀,
26. Ẹniti a fi ẹ̀tan bò irira rẹ̀ mọlẹ, ìwa-buburu rẹ̀ li a o fi hàn niwaju gbogbo ijọ:
27. Ẹnikẹni ti o ba wà ihò yio ṣubu sinu rẹ̀: ẹniti o ba si nyi okuta, on ni yio pada tọ̀.
28. Ahọn eke korira awọn ti a fi njẹniya; ẹnu ipọnni a si ma ṣiṣẹ iparun.