25. Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn.
26. Ọmọ mi, fi aiya rẹ fun mi, ki o si jẹ ki oju rẹ ki o ni inu-didùn si ọ̀na mi.
27. Nitoripe agbere, iho jijin ni; ati ajeji obinrin, iho hiha ni.
28. On a si ba ni ibuba bi ole, a si sọ awọn olurekọja di pupọ ninu awọn enia.
29. Tali o ni òṣi? tali o ni ibinujẹ? tali o ni ijà? tali o ni asọ̀? tali o ni ọgbẹ lainidi, tali o ni oju pipọn.