16. Inu mi yio si dùn nigbati ètè rẹ ba nsọ̀rọ titọ.
17. Máṣe jẹ ki aiya rẹ ki o ṣe ilara si awọn ẹ̀lẹṣẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o wà ni ibẹ̀ru Oluwa, li ọjọ gbogbo.
18. Nitoripe ikẹhin mbẹ nitõtọ; ireti rẹ kì yio si ke kuro.
19. Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki iwọ ki o si gbọ́n, ki iwọ ki o si ma tọ́ aiya rẹ si ọ̀na titọ.
20. Máṣe wà ninu awọn ọmuti; ninu awọn ti mba ẹran-ara awọn tikarawọn jẹ.
21. Nitoripe ọmuti ati ọjẹun ni yio di talaka; ọlẹ ni yio si fi akisa bò ara rẹ̀.