Owe 21:14-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ọrẹ ikọkọ, o tù ibinu: ati ẹ̀bun ni iṣẹpo-aṣọ, o tù ibinu lile.

15. Ayọ̀ ni fun olododo lati ṣe idajọ: ṣugbọn iparun ni fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.

16. Ẹniti o ba yà kuro li ọ̀na oye, yio ma gbe inu ijọ awọn okú.

17. Ẹniti o ba fẹ afẹ, yio di talaka: ẹniti o fẹ ọti-waini pẹlu ororo kò le lọrọ̀.

18. Enia buburu ni yio ṣe owo-irapada fun olododo, ati olurekọja ni ipò ẹni diduro-ṣinṣin.

19. O san lati joko li aginju jù pẹlu onija obinrin ati oṣónu lọ.

20. Iṣura fifẹ ati ororo wà ni ibugbe ọlọgbọ́n; ṣugbọn enia aṣiwère ná a bajẹ.

21. Ẹniti o ba tẹle ododo ati ãnu, a ri ìye, ododo, ati ọlá.

22. Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀.

23. Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kuro ninu iyọnu.

24. Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ.

Owe 21