Owe 20:27-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ẹmi enia ni fitila Oluwa, a ma ṣe awari iyara inu.

28. Anu ati otitọ pa ọba mọ́: ãnu li a si fi ndi itẹ́ rẹ̀ mu.

29. Ogo awọn ọdọmọkunrin li agbara wọn: ẹwà awọn arugbo li ewú.

30. Apá ọgbẹ ni iwẹ̀ ibi nù kuro: bẹ̃ si ni ìna ti o wọ̀ odò ikùn lọ.

Owe 20