Owe 2:13-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ẹniti o fi ipa-ọ̀na iduroṣinṣin silẹ, lati rìn li ọ̀na òkunkun;

14. Ẹniti o yọ̀ ni buburu iṣe, ti o ṣe inu-didùn si ayidàyidà awọn enia buburu;

15. Ọ̀na ẹniti o wọ́, nwọn si ṣe arekereke ni ipa-ọ̀na wọn:

16. Lati gbà ọ li ọwọ ajeji obinrin, ani li ọwọ ajeji obinrin ti nfi ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ pọnni;

17. Ẹniti o kọ̀ ọrẹ́ igbà-ewe rẹ̀ silẹ, ti o si gbagbe majẹmu Ọlọrun rẹ̀.

18. Nitoripe ile rẹ̀ tẹ̀ sinu ikú, ati ipa-ọ̀na rẹ̀ sọdọ awọn okú.

19. Kò si ẹniti o tọ̀ ọ lọ ti o si tun pada sẹhin, bẹ̃ni nwọn kì idé ipa-ọ̀na ìye.

Owe 2