Owe 19:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. TALAKA ti nrìn ninu ìwa-titọ rẹ̀, o san jù ẹniti o nṣe arekereke li ète rẹ̀ lọ, ti o si nṣe wère.

2. Pẹlupẹlu, ọkàn laini ìmọ, kò dara; ẹniti o ba si fi ẹsẹ rẹ̀ yara yio ṣubu.

3. Wère enia yi ọ̀na rẹ̀ po: nigbana ni aiya rẹ̀ binu si Oluwa.

4. Ọrọ̀ fà ọrẹ́ pupọ; ṣugbọn talaka di yiyà kuro lọdọ aladugbo rẹ̀.

5. Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ati ẹniti o si nṣeke kì yio mu u jẹ.

6. Ọpọlọpọ ni yio ma bẹ̀bẹ ojurere ọmọ-alade: olukuluku enia ni si iṣe ọrẹ́ ẹniti ntani li ọrẹ.

Owe 19