Owe 17:25-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Aṣiwère ọmọ ni ibinujẹ baba rẹ̀, ati kikoro ọkàn fun iya ti o bi i.

26. Pẹlupẹlu kò dara ki a ṣẹ́ olotitọ ni iṣẹ́, tabi ki a lu ọmọ-alade nitori iṣedẽde.

27. Ẹniti o ni ìmọ, a ṣẹ́ ọ̀rọ rẹ̀ kù: ọlọkàn tutu si li amoye enia.

28. Lõtọ, aṣiwère, nigbati o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́, a kà a si ọlọgbọ́n; ẹniti o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si li amoye.

Owe 17