13. Ẹnikẹni ti o ba fi ibi san ire, ibi kì yio kuro ninu ile rẹ̀.
14. Ẹniti o daju fun omi dabi olupilẹṣẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla.
15. Ẹniti o da enia buburu lare, ati ẹniti o da olododo lẹbi, ani awọn mejeji irira ni loju Oluwa.
16. Nitori kini iye owo yio ṣe wà lọwọ aṣiwère lati rà ọgbọ́n, sa wò o, kò ni oye?
17. Ọrẹ́ a ma fẹni nigbagbogbo, ṣugbọn arakunrin li a bi fun ìgba ipọnju.
18. Enia ti oye kù fun, a ṣe onigbọwọ, a si fi ara sọfà niwaju ọrẹ́ rẹ̀.
19. Ẹniti o fẹ ìja, o fẹ ẹ̀ṣẹ; ẹniti o kọ́ ẹnu-ọ̀na rẹ̀ ga, o nwá iparun.
20. Ẹniti o ni ayidayida ọkàn kì yio ri ire: ati ẹniti o ni ahọn ọ̀rọ-meji, a bọ sinu ibi.
21. Ẹniti o bi aṣiwère, o bi i si ibinujẹ rẹ̀; baba aṣiwère kò si li ayọ̀.
22. Inu-didùn mu imularada rere wá: ṣugbọn ibinujẹ ọkàn mu egungun gbẹ.
23. Enia buburu mu ẹ̀bun lati iṣẹpo-aṣọ lati yi ọ̀na idajọ pada.
24. Ọgbọ́n wà niwaju ẹniti o moye; ṣugbọn oju aṣiwère mbẹ li opin ilẹ̀-aiye.