1. OKELE gbigbẹ, ti on ti alafia, o san jù ile ti o kún fun ẹran-pipa ti on ti ìja.
2. Ọlọgbọ́n iranṣẹ yio ṣe olori ọmọ ti nhùwa itiju, yio si pin ogún lãrin awọn arakunrin.
3. Koro ni fun fadaka, ati ileru fun wura: bẹ̃li Oluwa ndan aiya wò.
4. Oluṣe buburu fetisi ète eke; ẹni-eké a si ma kiyesi ọ̀rọ ahọn buburu.
5. Ẹnikẹni ti o ba sín olupọnju jẹ, o gàn Ẹlẹda rẹ̀: ẹniti o ba si nyọ̀ si wahala kì yio wà li aijiya.
6. Ọmọ ọmọ li ade arugbo: ogo awọn ọmọ si ni baba wọn.
7. Ọ̀rọ daradara kò yẹ fun aṣiwère; bẹ̃li ète eke kò yẹ fun ọmọ-alade.
8. Okuta iyebiye jẹ ẹ̀bun li oju ẹniti o ni i; nibikibi ti o yi si, a ṣe rere.
9. Ẹniti o bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ, o nwá ifẹ; ṣugbọn ẹniti o tun ọ̀ran hú silẹ, o yà ọrẹ́ nipa.
10. Ibawi wọ̀ inu ọlọgbọ́n jù ọgọrun paṣan lọ ninu aṣiwère.
11. Ẹni-ọ̀tẹ a ma wá kiki ibi kiri; nitorina iranṣẹ ìka li a o ran si i.
12. O yá ki ẹranko beari ti a kó li ọmọ ki o pade enia, jù aṣiwère lọ ninu wère rẹ̀.
13. Ẹnikẹni ti o ba fi ibi san ire, ibi kì yio kuro ninu ile rẹ̀.
14. Ẹniti o daju fun omi dabi olupilẹṣẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla.
15. Ẹniti o da enia buburu lare, ati ẹniti o da olododo lẹbi, ani awọn mejeji irira ni loju Oluwa.
16. Nitori kini iye owo yio ṣe wà lọwọ aṣiwère lati rà ọgbọ́n, sa wò o, kò ni oye?
17. Ọrẹ́ a ma fẹni nigbagbogbo, ṣugbọn arakunrin li a bi fun ìgba ipọnju.