11. Ipo-okú ati iparun ṣi silẹ niwaju Oluwa; njẹ melomelo li aiya awọn ọmọ enia.
12. Ẹlẹgàn kò fẹ ẹniti mba a wi; bẹ̃ni kì yio tọ̀ awọn ọlọgbọ́n lọ.
13. Inu-didùn a mu oju daraya; ṣugbọn nipa ibinujẹ aiya, ọkàn a rẹ̀wẹsi.
14. Aiya ẹniti oye ye nṣe afẹri ìmọ; ṣugbọn ẹnu aṣiwère nfi wère bọ́ ara rẹ̀.
15. Gbogbo ọjọ olupọnju ni ibi; ṣugbọn oninu-didùn njẹ alafia nigbagbogbo.
16. Diẹ pẹlu ibẹ̀ru Oluwa, o san jù iṣura pupọ ti on ti iyọnu ninu rẹ̀.
17. Onjẹ ewebẹ̀ nibiti ifẹ wà, o san jù abọpa malu lọ ati irira pẹlu rẹ̀.
18. Abinu enia rú asọ̀ soke; ṣugbọn ẹniti o lọra ati binu, o tù ìja ninu.
19. Ọna ọlẹ dabi igbo ẹgún; ṣugbọn ọ̀na olododo já gẽrege ni.
20. Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe ayọ̀ baba; ṣugbọn aṣiwère enia gàn iya rẹ̀.
21. Ayọ̀ ni wère fun ẹniti oye kù fun; ṣugbọn ẹni-oye a ma rìn ni iduroṣinṣin.
22. Laisi ìgbimọ, èro a dasan; ṣugbọn li ọ̀pọlọpọ ìgbimọ, nwọn a fi idi mulẹ.
23. Enia ni ayọ̀ nipa idahùn ẹnu rẹ̀; ati ọ̀rọ kan li akoko rẹ̀, o ti wọ̀ to?
24. Ọ̀na ìye lọ soke fun ọlọgbọ́n, ki o le kuro ni ipo-okú nisalẹ.
25. Oluwa yio run ile agberaga; ṣugbọn yio fi ìpãlà opó kalẹ.
26. Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀.
27. Ẹniti o njẹ ère aiṣododo, o nyọ ile ara rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn ẹniti o korira ẹ̀bun yio yè.