32. A pa enia buburu run ninu ìwa-buburu rẹ̀; ṣugbọn olododo ni ireti ninu ikú rẹ̀.
33. Ọgbọ́n fi idi kalẹ li aiya ẹniti o moye; ṣugbọn a fi i hàn laiya awọn aṣiwère.
34. Ododo ni igbé orilẹ-ède leke; ṣugbọn ẹ̀ṣẹ li ẹ̀gan orilẹ-ède.
35. Ojurere ọba mbẹ li ọdọ ọlọgbọ́n iranṣẹ; ṣugbọn ibinu rẹ̀ si iranṣẹ ti nhùwa itiju.