Owe 13:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe ọlọrọ̀, ṣugbọn kò ni nkan; ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe talaka ṣugbọn o li ọrọ̀ pupọ.

8. Irapada ẹmi enia li ọrọ̀ rẹ̀; ṣugbọn olupọnju kò kiyesi ibawi.

9. Imọlẹ olododo nfi ayọ̀ jó; ṣugbọn fitila enia buburu li a o pa.

10. Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà.

11. Ọrọ̀ ti a fi ìwa-asan ni yio fàsẹhin; ṣugbọn ẹniti o fi iṣẹ-ọwọ kojọ ni yio ma pọ̀ si i.

12. Ireti pipẹ mu ọkàn ṣàisan; ṣugbọn nigbati ifẹ ba de, igi ìye ni.

13. Ẹnikan ti o ba gàn ọ̀rọ na li a o parun: ṣugbọn ẹniti o bẹ̀ru ofin na, li a o san pada fun.

14. Ofin ọlọgbọ́n li orisun ìye, lati kuro ninu okùn ikú.

Owe 13