23. Onjẹ pupọ li o wà ni ilẹ titun awọn talaka; ṣugbọn awọn kan wà ti a nparun nitori aini idajọ;
24. Ẹniti o ba fà ọwọ paṣan sẹhin, o korira ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o fẹ ẹ a ma tète nà a.
25. Olododo jẹ to itẹrun ọkàn rẹ̀; ṣugbọn inu awọn enia buburu ni yio ṣe alaini.