Owe 12:8-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. A o yìn enia gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ̀: ṣugbọn ẹni alayidayida aiya li a o gàn.

9. Ẹniti a ngàn, ti o si ni ọmọ-ọdọ, o san jù ẹ̀niti nyìn ara rẹ̀ ti kò si ni onjẹ.

10. Olododo enia mọ̀ ãjo ẹmi ẹran rẹ̀: ṣugbọn iyọ́nu awọn enia buburu, ìka ni.

Owe 12