13. Irekọja ète enia buburu li a fi idẹkùn rẹ̀: ṣugbọn olododo yio yọ kuro ninu ipọnju.
14. Nipa ère ẹnu enia li a o fi ohun rere tẹ ẹ lọrun: ère-iṣẹ ọwọ enia li a o si san fun u.
15. Ọ̀na aṣiwere tọ li oju ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọ́n.
16. Ibinu aṣiwere kò pẹ imọ̀: ṣugbọn amoye enia bò itiju mọlẹ.
17. Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan.
18. Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni.