9. Ẹnu li agabagebe ifi pa aladugbo rẹ̀: ṣugbọn ìmọ li a o fi gbà awọn olododo silẹ.
10. Nigbati o ba nṣe rere fun olododo, ilu a yọ̀: nigbati enia buburu ba ṣegbe, igbe-ayọ̀ a ta.
11. Nipa ibukún aduro-ṣinṣin ilu a gbé lèke: ṣugbọn a bì i ṣubu nipa ẹnu enia buburu.
12. Ẹniti oye kù fun gàn ọmọnikeji rẹ̀; ṣugbọn ẹni oye a pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
13. Ẹniti nṣofofo fi ọ̀ran ipamọ́ hàn; ṣugbọn ẹniti nṣe olõtọ-ọkàn a pa ọ̀rọ na mọ́.
14. Nibiti ìgbimọ kò si, awọn enia a ṣubu; ṣugbọn ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni ailewu.
15. Ẹniti o ba ṣe onigbọwọ fun alejo, ni yio ri iyọnu; ẹniti o ba si korira iṣegbọwọ wà lailewu.
16. Obinrin olore-ọfẹ gbà iyìn: bi alagbara enia ti igbà ọrọ̀.
17. Alãnu enia ṣe rere fun ara rẹ̀: ṣugbọn ìka-enia nyọ ẹran-ara rẹ̀ li ẹnu.
18. Enia buburu nṣiṣẹ ère-ẹ̀tan; ṣugbọn ẹniti ngbin ododo ni ère otitọ wà fun.
19. Bi ẹniti o duro ninu ododo ti ini ìye, bẹ̃ni ẹniti nlepa ibi, o nle e si ikú ara rẹ̀.
20. Awọn ti iṣe alarekereke aiya, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn inu rẹ̀ dùn si awọn aduroṣinṣin: