Owe 11:17-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Alãnu enia ṣe rere fun ara rẹ̀: ṣugbọn ìka-enia nyọ ẹran-ara rẹ̀ li ẹnu.

18. Enia buburu nṣiṣẹ ère-ẹ̀tan; ṣugbọn ẹniti ngbin ododo ni ère otitọ wà fun.

19. Bi ẹniti o duro ninu ododo ti ini ìye, bẹ̃ni ẹniti nlepa ibi, o nle e si ikú ara rẹ̀.

Owe 11