18. Awọn wọnyi si ba fun ẹ̀jẹ ara wọn; nwọn lumọ nikọkọ fun ẹmi ara wọn.
19. Bẹ̃ni ọ̀na gbogbo awọn ti nṣe ojukokoro ère; ti ngba ẹmi awọn oluwa ohun na.
20. Ọgbọ́n nkigbe lode; o nfọhùn rẹ̀ ni igboro:
21. O nke ni ibi pataki apejọ, ni gbangba ẹnubode ilu, o sọ ọ̀rọ rẹ̀ wipe,
22. Yio ti pẹ tó, ẹnyin alaimọ̀kan ti ẹnyin o fi ma fẹ aimọ̀kan? ati ti awọn ẹlẹgàn yio fi ma ṣe inudidùn ninu ẹ̀gan wọn, ati ti awọn aṣiwere yio fi ma korira ìmọ?
23. Ẹ yipada ni ibawi mi; kiyesi i, emi o dà ẹmi mi sinu nyin, emi o fi ọ̀rọ mi hàn fun nyin.
24. Nitori ti emi pè, ti ẹnyin si kọ̀; ti emi nà ọwọ mi, ti ẹnikan kò si kà a si:
25. Ṣugbọn ẹnyin ti ṣá gbogbo ìgbimọ mi tì, ẹnyin kò si fẹ ibawi mi:
26. Emi pẹlu o rẹrin idãmu nyin; emi o ṣe ẹ̀fẹ nigbati ibẹ̀ru nyin ba de;
27. Nigbati ibẹ̀ru nyin ba de bi ìji, ati idãmu nyin bi afẹyika-ìji; nigbati wahala ati àrodun ba de si nyin.
28. Nigbana ni ẹnyin o kepè mi, ṣugbọn emi kì yio dahùn; nwọn o ṣafẹri mi ni kùtukùtu, ṣugbọn nwọn kì yio ri mi:
29. Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa.
30. Nwọn kò fẹ ìgbimọ mi: nwọn gàn gbogbo ibawi mi.
31. Nitorina ni nwọn o ṣe ma jẹ ninu ère ìwa ara wọn, nwọn o si kún fun ìmọkimọ wọn.