1. OWE Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli;
2. Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ̀ ọ̀rọ oye;
3. Lati gbà ẹkọ́ ọgbọ́n, ododo, ati idajọ, ati aiṣègbe;
4. Lati fi oye fun alaimọ̀kan, lati fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati ironu.
5. Ọlọgbọ́n yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ́; ati ẹni oye yio gba igbimọ̀ ọgbọ́n:
6. Lati mọ̀ owe, ati ìtumọ; ọ̀rọ ọgbọ́n, ati ọ̀rọ ikọkọ wọn.
7. Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́.
8. Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ̀ ofin iya rẹ silẹ:
9. Nitoripe awọn ni yio ṣe ade ẹwà fun ori rẹ, ati ọṣọ́ yi ọrùn rẹ ka.
10. Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà.