27. Kiyesi i, eyi ni mo ri, bẹ̃li oniwasu wi, ni wiwadi rẹ̀ li ọkọkan lati ri oye.
28. Ti ọkàn mi nwakiri sibẹ, ṣugbọn emi kò ri: ọkunrin kanṣoṣo ninu ẹgbẹrun ni mo ri; ṣugbọn obinrin kan ninu gbogbo awọn wọnni, emi kò ri.
29. Kiyesi i, eyi nikanṣoṣo ni mo ri, pe, Ọlọrun ti da enia ni iduroṣinṣin; ṣugbọn nwọn ti ṣe afẹri ihumọkihumọ.