7. Gbogbo lãla enia ni fun ẹnu rẹ̀, ṣugbọn a kò ti itẹ adùn ọkàn rẹ̀ lọrun.
8. Nitoripe ère kili ọlọgbọ́n ni jù aṣiwère lọ? kini talaka ni ti o mọ̀ bi a ti rin niwaju awọn alãye?
9. Eyiti oju ri san jù irokakiri ifẹ lọ; asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.
10. Eyi ti o wà, a ti da orukọ rẹ̀ ri, a si ti mọ̀ ọ pe, enia ni: bẹ̃ni kò le ba ẹniti o lagbara jù u lọ jà.
11. Kiyesi i ohun pupọ li o wà ti nmu asan bi si i, ère kili enia ni?
12. Nitoripe tali o mọ̀ ohun ti o dara fun enia li aiye yi, ni iye ọjọ asan rẹ̀ ti nlọ bi ojiji? nitoripe tali o le sọ fun enia li ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀ labẹ õrùn?