5. Aṣiwère fọwọ rẹ̀ lọwọ, o si njẹ ẹran-ara rẹ̀.
6. Onjẹ ikunwọ kan pẹlu idakẹjẹ, o san jù ikunwọ meji lọ ti o kun fun lãla ati imulẹmofo.
7. Nigbana ni mo pada, mo si ri asan labẹ õrun.
8. Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi.