Oni 4:4-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ati pẹlu, mo rò gbogbo lãla ati ìmọ iṣẹ gbogbo, pe eyiyi ni ilara ẹnikini lati ọdọ ẹnikeji rẹ̀. Asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.

5. Aṣiwère fọwọ rẹ̀ lọwọ, o si njẹ ẹran-ara rẹ̀.

6. Onjẹ ikunwọ kan pẹlu idakẹjẹ, o san jù ikunwọ meji lọ ti o kun fun lãla ati imulẹmofo.

7. Nigbana ni mo pada, mo si ri asan labẹ õrun.

8. Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi.

9. Ẹni meji san jù ẹnikan; nitori nwọn ni ère rere fun lãla wọn.

10. Nitoripe bi nwọn ba ṣubu, ẹnikini yio gbe ọ̀gba rẹ̀ dide: ṣugbọn egbe ni fun ẹniti o ṣe on nikan nigbati o ba ṣubu; ti kò li ẹlomiran ti yio gbé e dide.

11. Ati pẹlu, bi ẹni meji ba dubulẹ pọ̀, nigbana ni nwọn o mõru: ṣugbọn ẹnikan yio ha ti ṣe mõru?

12. Bi ẹnikan ba kọlu ẹnikan, ẹni meji yio kò o loju; ati okùn onikọ mẹta kì iyá fàja.

13. Otoṣi ipẹ̃rẹ ti o ṣe ọlọgbọ́n, o san jù arugbo ati aṣiwère ọba lọ ti kò mọ̀ bi a ti igbà ìmọran.

14. Nitoripe lati inu tubu li o ti jade wá ijọba; bi a tilẹ ti bi i ni talaka ni ijọba rẹ̀.

Oni 4