Oni 4:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BẸ̃NI mo pada, mo si rò inilara gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn; mo si wò omije awọn ti a nnilara, nwọn kò si ni olutunu; ati lọwọ aninilara wọn ni ipá wà; ṣugbọn nwọn kò ni olutunu.

2. Nitorina mo yìn okú ti o ti kú pẹ jù awọn alãye ti o wà lãye sibẹ.

3. Nitõtọ, ẹniti kò ti isi san jù awọn mejeji; ẹniti kò ti iri iṣẹ buburu ti a nṣe labẹ õrùn.

4. Ati pẹlu, mo rò gbogbo lãla ati ìmọ iṣẹ gbogbo, pe eyiyi ni ilara ẹnikini lati ọdọ ẹnikeji rẹ̀. Asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.

Oni 4