Oni 3:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ìgba sisọkun ati ìgba rirẹrín; ìgba ṣiṣọ̀fọ ati igba jijo;

5. Ìgba kikó okuta danu, ati ìgba kiko okuta jọ; ìgba fifọwọkoni mọra, ati ìgba fifasẹhin ni fifọwọkoni mọra;

6. Ìgba wiwari, ati ìgba sísọnu: ìgba pipamọ́ ati ìgba ṣiṣa tì;

7. Ìgba fifaya, ati ìgba rirán; ìgba didakẹ, ati ìgba fifọhùn;

8. Ìgba fifẹ, ati ìgba kikorira; ìgba ogun, ati ìgba alafia.

9. Ere kili ẹniti nṣiṣẹ ni ninu eyiti o nṣe lãla?

10. Mo ti ri ìṣẹ́ ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ enia lati ma ṣíṣẹ ninu rẹ̀.

11. O ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgba tirẹ̀; pẹlupẹlu o fi aiyeraiye si wọn li aiya, bẹ̃li ẹnikan kò le ridi iṣẹ na ti Ọlọrun nṣe lati ipilẹṣẹ titi de opin.

12. Emi mọ̀ pe kò si rere ninu wọn, bikoṣe ki enia ki o ma yọ̀, ki o si ma ṣe rere li aiya rẹ̀.

Oni 3