Oni 3:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ìgba pipa ati ìgba imularada; ìgba wiwo lulẹ ati ìgba kikọ;

4. Ìgba sisọkun ati ìgba rirẹrín; ìgba ṣiṣọ̀fọ ati igba jijo;

5. Ìgba kikó okuta danu, ati ìgba kiko okuta jọ; ìgba fifọwọkoni mọra, ati ìgba fifasẹhin ni fifọwọkoni mọra;

6. Ìgba wiwari, ati ìgba sísọnu: ìgba pipamọ́ ati ìgba ṣiṣa tì;

7. Ìgba fifaya, ati ìgba rirán; ìgba didakẹ, ati ìgba fifọhùn;

8. Ìgba fifẹ, ati ìgba kikorira; ìgba ogun, ati ìgba alafia.

9. Ere kili ẹniti nṣiṣẹ ni ninu eyiti o nṣe lãla?

10. Mo ti ri ìṣẹ́ ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ enia lati ma ṣíṣẹ ninu rẹ̀.

Oni 3