Oni 12:9-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ati pẹlu, nitori Oniwasu na gbọ́n, o si nkọ́ awọn enia ni ìmọ pẹlu; nitõtọ o ṣe akiyesi daradara, o si wadi, o si fi owe pupọ lelẹ li ẹsẹsẹ.

10. Oniwasu wadi ati ri ọ̀rọ didùn eyiti a si kọ, ohun iduro-ṣinṣin ni, ani ọ̀rọ otitọ.

11. Ọ̀rọ ọlọgbọ́n dabi ẹgún, ati awọn olori akojọ-ọ̀rọ bi iṣó ti a kàn, ti a nfi fun ni lati ọwọ oluṣọ-agutan kan wá.

12. Ati siwaju, lati inu eyi, ọmọ mi, ki o gbà ìmọran: ninu kikọ iwe pupọ, opin kò si: ati iwe kikà pupọ li ãrẹ̀ ara.

13. Opin gbogbo ọ̀rọ na ti a gbọ́ ni pe: Bẹ̀ru Ọlọrun ki o si pa ofin rẹ̀ mọ́: nitori eyi ni fun gbogbo enia.

14. Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.

Oni 12