Oni 11:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. FUN onjẹ rẹ si oju omi; nitoriti iwọ o ri i lẹhin ọjọ pupọ.

2. Fi ipin fun meje ati fun mẹjọ pẹlu, nitoriti iwọ kò mọ̀ ibi ti yio wà laiye.

3. Bi awọsanma ba kún fun òjo, nwọn a si tu dà si aiye: bi igi ba si wó sìha gusu tabi siha ariwa, nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe.

4. Ẹniti o nkiyesi afẹfẹ kì yio funrugbin; ati ẹniti o si nwòju awọsanma kì yio ṣe ikore.

5. Bi iwọ kò ti mọ ipa-ọ̀na afẹfẹ, tabi bi egungun ti idàgba ninu aboyun: ani bẹ̃ni iwọ kò le mọ̀ iṣẹ Ọlọrun ti nṣe ohun gbogbo.

Oni 11