Oni 1:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ere kili enia jẹ ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn?

4. Iran kan lọ, iran miran si bọ̀: ṣugbọn aiye duro titi lai.

5. Õrun pẹlu là, õrun si wọ̀, o si yara lọ si ipò rẹ̀ nibiti o ti là.

6. Afẹfẹ nfẹ lọ siha gusu, a si yipada siha ariwa; o si nlọ sihin sọhun titi, afẹfẹ si tun pada gẹgẹ nipa ayika rẹ̀.

7. Odò gbogbo ni nṣan sinu okun; ṣugbọn okun kò kún, nibiti awọn odò ti nṣàn wá, nibẹ ni nwọn si tun pada lọ.

8. Ọ̀rọ gbogbo kò to; enia kò le sọ ọ: iran kì isu oju, bẹ̃li eti kì ikún fun gbigbọ́.

9. Ohun ti o wà, on ni yio si wà; ati eyiti a ti ṣe li eyi ti a o ṣe; kò si ohun titun labẹ õrùn.

10. Ohun kan wà nipa eyi ti a wipe, Wò o, titun li eyi! o ti wà na nigba atijọ, ti o ti wà ṣaju wa.

11. Kò si iranti ohun iṣaju; bẹ̃ni iranti kì yio si fun ohun ikẹhin ti mbọ̀, lọdọ awọn ti mbọ̀ ni igba ikẹhin.

Oni 1