2. Asan inu asan, oniwasu na wipe, asan inu asan; gbogbo rẹ̀ asan ni!
3. Ere kili enia jẹ ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn?
4. Iran kan lọ, iran miran si bọ̀: ṣugbọn aiye duro titi lai.
5. Õrun pẹlu là, õrun si wọ̀, o si yara lọ si ipò rẹ̀ nibiti o ti là.
6. Afẹfẹ nfẹ lọ siha gusu, a si yipada siha ariwa; o si nlọ sihin sọhun titi, afẹfẹ si tun pada gẹgẹ nipa ayika rẹ̀.
7. Odò gbogbo ni nṣan sinu okun; ṣugbọn okun kò kún, nibiti awọn odò ti nṣàn wá, nibẹ ni nwọn si tun pada lọ.
8. Ọ̀rọ gbogbo kò to; enia kò le sọ ọ: iran kì isu oju, bẹ̃li eti kì ikún fun gbigbọ́.