1. Ọ̀RỌ oniwasu, ọmọ Dafidi, ti o jọba ni Jerusalemu.
2. Asan inu asan, oniwasu na wipe, asan inu asan; gbogbo rẹ̀ asan ni!
3. Ere kili enia jẹ ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn?
4. Iran kan lọ, iran miran si bọ̀: ṣugbọn aiye duro titi lai.
5. Õrun pẹlu là, õrun si wọ̀, o si yara lọ si ipò rẹ̀ nibiti o ti là.
6. Afẹfẹ nfẹ lọ siha gusu, a si yipada siha ariwa; o si nlọ sihin sọhun titi, afẹfẹ si tun pada gẹgẹ nipa ayika rẹ̀.