7. Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata.
8. Awa ni arabinrin kekere kan, on kò si ni ọmú: kili awa o ṣe fun arabinrin wa li ọjọ ti a o ba fẹ ẹ?
9. Bi on ba ṣe ogiri, awa o kọ́ ile-odi fadaka le e lori: bi on ba si ṣe ẹnu-ọ̀na, awa o fi apako kedari dí i.
10. Ogiri ni mi, ọmú mi sì dabi ile-iṣọ: nigbana loju rẹ̀ mo dabi ẹniti o ri alafia.
11. Solomoni ni ọgba-àjara kan ni Baalhamoni; o fi ọgba-àjara na ṣe ọ̀ya fun awọn oluṣọ; olukuluku ni imu ẹgbẹrun fadaka wá nipò eso rẹ̀.
12. Ọgba-àjara mi, ti iṣe temi, o wà niwaju mi: iwọ Solomoni yio ni ẹgbẹrun fadaka, ati awọn ti nṣọ eso na yio ni igba.
13. Iwọ ti ngbe inu ọgbà, awọn ẹgbẹ rẹ fetisi ohùn rẹ: mu mi gbọ́ ọ pẹlu.