O. Sol 8:11-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Solomoni ni ọgba-àjara kan ni Baalhamoni; o fi ọgba-àjara na ṣe ọ̀ya fun awọn oluṣọ; olukuluku ni imu ẹgbẹrun fadaka wá nipò eso rẹ̀.

12. Ọgba-àjara mi, ti iṣe temi, o wà niwaju mi: iwọ Solomoni yio ni ẹgbẹrun fadaka, ati awọn ti nṣọ eso na yio ni igba.

13. Iwọ ti ngbe inu ọgbà, awọn ẹgbẹ rẹ fetisi ohùn rẹ: mu mi gbọ́ ọ pẹlu.

14. Yara, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin tabi ọmọ agbọnrin lori òke õrùn didùn.

O. Sol 8